bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 27
Proverbs 27
Yoruba 2010
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
1
Má lérí nípa ọ̀la, nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
2
Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ, jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde, kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.
3
Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.
4
Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ, ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?
5
Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.
6
Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́; ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.
7
Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú, ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn, lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8
Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀, dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.
9
Òróró ati turari a máa mú inú dùn, ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.
10
Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ; má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ. Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.
11
Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn, kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.
12
Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.
13
Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò, kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.
14
Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀, tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.
15
Iyawo oníjà dàbí omi òjò, tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;
16
ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró, tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.
17
Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
18
Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ, ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.
19
Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
20
Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.
21
Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò, ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.
22
Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó, kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà, ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
23
Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí, sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;
24
nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí, kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.
25
Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù, tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,
26
o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ, o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.
27
O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu, ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31