bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Proverbs 25
Proverbs 25
Yoruba 2010
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 26 →
1
Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí.
2
Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́, ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọba láti wádìí nǹkan ní àwárí.
3
Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba.
4
Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò, alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò.
5
Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba, a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.
6
Má ṣe gbéraga níwájú ọba, tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,
7
nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”, jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.
8
Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́, nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.
9
Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyàn má ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,
10
kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́, kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.
11
Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.
12
Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà, tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe, fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.
13
Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè, bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an, a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.
14
Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títí ṣugbọn tí kò rọ̀, ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn, tí kò sì fúnni ní nǹkankan.
15
Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn pada ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.
16
Bí o bá rí oyin, lá a níwọ̀nba, má lá a ní àlájù, kí o má baà bì.
17
Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́, kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ.
18
Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀ dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.
19
Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro, dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.
20
Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù, tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀, ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.
21
Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
22
Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí, OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ.
23
Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá, bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.
24
Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà, ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.
25
Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí.
26
Olódodo tí ó fi ààyè sílẹ̀ fún eniyan burúkú dàbí odò tí omi rẹ̀ dàrú tabi kànga tí a da ìdọ̀tí sí.
27
Kò dára kí eniyan lá oyin ní àlájù, bẹ́ẹ̀ ni kò dára kí eniyan máa wá iyì ní àwájù.
28
Ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, dàbí ìlú tí ọ̀tá wọ̀, tí wọ́n sì wó odi rẹ̀ lulẹ̀.
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31