bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 1
Isaiah 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
1
Ìran sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí ní àsìkò ìjọba Hùṣáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà.
2
Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí OLÚWA ti sọrọ̀: “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
3
Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
4
Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, Ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ OLÚWA sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
5
Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́? Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.
6
Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
7
Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀.
8
Ọmọbìnrin Ṣíónì ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí àbá nínú oko ẹ̀gúsí, àti bí ìlú tí a dótì.
9
Àyàfi bí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun bá sẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sódómù, a ò bá sì ti dàbí Gòmórà.
10
Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin aláṣẹ Sódómù, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà!
11
“Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni OLÚWA wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti orúkọ.
12
Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín, Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
13
Ẹ má mú ọrẹ aṣán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun, ọjọ́ ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpèjọ Èmi kò lè faradà àpèjọ ibi yín wọ̀nyí.
14
Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹ tí ẹ yà ṣọ́tọ̀ ni ọkàn mi kórìíra. Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n.
15
Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́ti sí i. Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
16
Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́. Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi! Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
17
kọ́ láti ṣe rere! Wá ìdájọ́ òtítọ́, tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú. Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, gbà ẹjọ́ opó rò.
18
“Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,” ni OLÚWA wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.
19
Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn, ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
20
Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀, idà ni a ó fi pa yín run.” Nítorí ẹnu OLÚWA la ti sọ ọ́.
21
Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè! Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!
22
Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́, ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là.
23
Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn.
24
Nítorí náà ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Alágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.
25
Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26
Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
27
A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà, àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo.
28
Ṣùgbọn àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó pa run Àwọn tí ó bá sì kọ OLÚWA sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
29
“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín.
30
Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ tí, tàbí bí ọgbà tí kò ní omi.
31
Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí lẹ́ù iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná, àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀, láì sí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66