bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 36
Isaiah 36
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 35
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 37 →
1
Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Heṣekáyà, Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Júdà ó sì kó gbogbo wọn.
2
Lẹ́yìn náà, ọba Áṣíríà rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì sí ọba Hẹṣikáyà ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúsàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀,
3
Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.
4
Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Heṣekáyà, “ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé: Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?
5
Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ aṣán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?
6
Wò ó nísinsìn yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì ẹ̀rúnrún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sìí dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.
7
Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Heṣekáyà ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájúu pẹpẹ yìí”?
8
“ ‘Ẹ wá nísinsìn yìí, bá ọ̀gá mi pàmọ̀ pọ̀, ọba Ásíríà: Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!
9
Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kanṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn ìjòyè ọ̀gá mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?
10
Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí OLÚWA? OLÚWA fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀ èdè yìí jà kí n sì paárun.’ ”
11
Lẹ́yìn náà ni Eliákímù, Ṣébínà àti Jóà sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”
12
Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà?”
13
Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké sítà ní èdè Hébérù pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà!
14
Ohun tí ọba wí nìyìí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀!
15
Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA nígbà tí ó sọ pé, ‘OLÚWA yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.’
16
“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Heṣekáyà. Ohun tí ọba Áṣíríà wí nìyìí: Ẹ ṣètò àlàáfíà pẹ̀lúù mi kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mumi nínú kàǹga rẹ̀,
17
títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i ti yín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
18
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà sì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘OLÚWA yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀ èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà bí?
19
Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Ápádì ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣépáfírámù ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Ṣamáríà gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí?
20
Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni OLÚWA ṣe wá le gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”
21
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”
22
Lẹ́yìn náà ni Eliákímù ọmọ Híkílíà alákóṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.
← Chapter 35
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 37 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→