bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 13
Isaiah 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 14 →
1
Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Bábílónì èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí:
2
Gbé àṣíá ṣókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu ọ̀nà àwọn Bọ̀rọ̀kìnní.
3
Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi, mo ti pe àwọn jagunjagun mi láti gbé ìbínú mi jáde àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
4
Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn Gbọ́, ìdàrúdàpọ̀ láàrin àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀ èdè! OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun.
5
Wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn réré, láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá OLÚWA pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú un rẹ̀— láti pa gbogbo orílẹ̀ èdè náà run.
6
Pohùnréré, nítorí ọjọ́ OLÚWA súnmọ́tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
7
Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ, ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
8
Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dì wọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkín-ín-ní yóò wo ẹnìkejìi rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sìgbinájẹ.
9
Kíyèsí i, ọjọ́ OLÚWA ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú un rẹ̀ run.
10
Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run ati ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ òòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
11
Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
12
Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówóo wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà ófírì lọ.
13
Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná an rẹ.
14
Gẹ́gẹ́ bí èkùlù tí à ń dọdẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
15
Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu, gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
16
Àwọn mọ̀jèsín wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn, gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.
17
Kíyèsí i, èmi yóò ru àwọn Mẹ́dísì sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
18
Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn mọ̀jèsín tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.
19
Bábílónì, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Bábílónì ni Ọlọ́run yóò dojúrẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sódómù àti Gòmórà.
20
A kì yóò sì gbé ibẹ̀ mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; Árábù kan yóò fi àgọ́ rẹ lélẹ̀ níbẹ̀, Olùsọ́ àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21
Ṣùgbọ́n àwọn ohun abẹ̀mí aṣálẹ̀ ni yóò gbé bẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwììwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́-igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
22
Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→