bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 34
Isaiah 34
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 35 →
1
Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tísílẹ̀ ẹyín ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú un rẹ̀ jáde.
2
Nítorí ibínú OLÚWA ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti irunú un rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn: o ti fi wọ́n fún pipa,
3
Àwọn ti a pa nínú un wọn ni a ó sì jù ṣóde, òórùn wọn yóò ti inú òkúu wọn jáde, àwọn òkè-ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn
4
Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i takàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èṣo lára igi ọ̀pọ̀tọ́.
5
Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsì í, yóò ṣọ̀kalẹ̀ wá sórí Édómù, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ.
6
Idà OLÚWA kún fún ẹ̀jẹ̀ a mú un ṣanra fún ọ̀rá, àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-agùtàn àti ewurẹ, fún ọ̀rá iwe àgbò— nítorí OLÚWA ni ìrúbọ kan ní Bósírà, àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Édómù.
7
Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá.
8
Nítorí ọjọ́ ẹ̀san OLÚWA ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Ṣíhónì.
9
Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà, àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́, ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.
10
A ki yóò paá ní òru tàbí ní ọ̀sán, èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé: yóò dahoro láti ìran dé ìran, kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé.
11
Ṣùgbọ́n ẹyẹ àṣá, àti àkàlà ni yóò ni ín, àti òun yóò sì na okùn-ìwọ̀n ìparun sóríi rẹ̀, àti òkúta ohun rudurùdu sórí àwọn ọlọ́lá rẹ̀.
12
Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ ti wọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olóríi rẹ̀ yóò sì di asán.
13
Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.
14
Àwọn ẹran ijù àti àwọn ọ̀wàwà ni yóò pàdé, àti sátírè kan yóò máa kọ sí èkejìí rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi isinmi fún ara rẹ̀.
15
Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.
16
Ẹ wá a nínú ìwé OLÚWA, ẹ sì kà á: Ọ̀kan nínú wọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ ìkejìi rẹ̀ kù: nítorí OLÚWA ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.
17
Ó ti di ìbò fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn nípa títa okùn, wọn ó jogún rẹ̀ láéláé, láti ìran dé ìran ni wọn ó máa gbé inú un rẹ̀.
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 35 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→