bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 3
Isaiah 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 4 →
1
Kíyèsí i, OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà gbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi
2
àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀sẹ àti alàgbà,
3
balógun àádọ́ta àti bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn, olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣegùn.
4
Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jọba lóríi wọn.
5
Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́n ọmọnìkejì wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.
6
Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọn arákùnrin rẹ̀ mú nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
7
Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé, “Èmi kò ní àtúnṣe kan. Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé, ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”
8
Jérúsálẹ́mù ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n Júdà ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí OLÚWA, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
9
Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
10
Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn.
11
Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọn A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.
12
Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí. Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.
13
OLÚWA bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
14
OLÚWA dojú ẹjọ́ kọ àwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15
Kín ni èro yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?” ni OLÚWA wí, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.
16
OLÚWA wí pé, “Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.
17
Nítorí náà OLÚWA yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, OLÚWA yóò sì pá wọn ní agbárí.”
18
Ní ọjọ́ náà, OLÚWA yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá
19
gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,
20
gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,
21
òrùka ọwọ́ àti ti imú,
22
àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,
23
Díńgí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.
24
Dípò òórùn dídùn, òórún búbubú ni yóò wá, okùn ni yóò wà dípò àmùrè, orí pípá ni yóò dípò ìrun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.
25
Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.
26
Àwọn bodè Síònì yóò sunkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀, nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66