bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 24
Isaiah 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 25 →
1
Kíyèsí i, OLÚWA yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
2
bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbésè.
3
Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapáta a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. OLÚWA ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
4
Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
5
àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
6
Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
7
Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora.
8
Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró ayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
9
Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10
Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11
Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12
Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.
13
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán.
14
Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀; láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọlá-ńlá OLÚWA.
15
Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún OLÚWA; gbé orúkọ OLÚWA ga, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,
16
Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!” “Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17
Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́, Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹkùn yóò gbámú. Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀ Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19
Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20
Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
21
Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò jẹ ẹ́ níyà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22
A ó dà wọ́n papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n tí a dè nínú un túbú, a ó tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23
A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti òòrùn; nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò jọba ní orí òkè Ṣíhónì àti ní Jérúsálẹ́mù, àti níwájú àwọn alàgbà rẹ ní ògo.
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66