bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 26
Isaiah 26
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 27 →
1
Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Júdà: Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀.
2
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀ èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀ èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
3
Ìwọ yóò paámọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4
Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA títí láé, nítorí OLÚWA, OLÚWA ni àpáta ayérayé náà.
5
Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹṣẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6
Ẹṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹṣẹ̀ aninilára n nì, ipaṣẹ̀ àwọn òtòsì.
7
Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú Ìwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo kúnná.
8
Bẹ́ẹ̀ ni, OLÚWA, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9
Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
10
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti ṣòdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọlá ńlá OLÚWA sí.
11
OLÚWA, ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀ta rẹ jó wọn run.
12
OLÚWA, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.
13
OLÚWA Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọọ̀ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
14
Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta.
15
Ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè gbòòrò, OLÚWA; ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè bí sí i. Ìwọ ti gba ògo fún araàrẹ; ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ ṣẹ́yìn.
16
OLÚWA, Wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njúu wọn; nígbà tí o jẹwọ́n ní ìyà, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ ẹ̀ má le gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́.
17
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ OLÚWA.
18
Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.
19
Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.
20
Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá.
21
Kíyèsíì, OLÚWA ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀, kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 27 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66