bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 44
Isaiah 44
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 43
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 45 →
1
“Ṣùgbọ́n tẹ́tísílẹ̀ nísinsìn yìí, Ìwọ Jákọ́bù, Ìránṣẹ́ mi Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn.
2
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú: Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi, Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.
3
Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ; Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
4
Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.
5
Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti OLÚWA’; òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù; bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti OLÚWA, yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.
6
“Ohun tí OLÚWA wí nìyìí ọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun: Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan.
7
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
8
Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
9
Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkankan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.
10
Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
11
Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójú tì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.
12
Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
13
Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀, Ó tún fi ṣísẹ́lì họ ọ́ jáde ó tún fi kọ́ḿpáásì ṣe àmì sí i. Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀, kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
14
Ó gé igi kédárì lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú Ṣípírẹ́sì tàbí óákù. Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
15
Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.
16
Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lóríi rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
17
Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀; ó forí balẹ̀ fún un, ó sì sìn ín. Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé, “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
18
Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan.
19
Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
20
Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ̀tàn ni ó sì í lọ́nà; òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
21
“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Ìwọ Jákọ́bù nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, Èmi Ísírẹ́lì, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
22
Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kùrukùru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
23
Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLÚWA ló ti ṣe èyí; kígbe ṣókè, Ìwọ ilẹ̀ ayé níṣàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí OLÚWA ti ra Jákọ́bù padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Ísírẹ́lì.
24
“Ohun tí OLÚWA wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni OLÚWA tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹṣẹ òun tìkálára rẹ̀,
25
“ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn tí ń woṣẹ́ fún ni di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọgbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
26
ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jérúsálẹ́mù pé, ‘a ó máa gbénú un rẹ̀,’ àti ní ti àwọn ìlú Júdà, ‘A ó tún un kọ́,’ àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀sípò,’
27
ta ni ó sọ fún omi jínjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
28
ta ni ó sọ nípa Ṣáírọ́ọ́ṣì pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, “Jẹ́ kí a tún un kọ́,” àti nípa tẹ́ḿpìlì, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’
← Chapter 43
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 45 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→