bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 60
Isaiah 60
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 59
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 61 →
1
“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo OLÚWA sì ràdọ̀bò ọ́.
2
Kíyèsí i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n OLÚWA ràn bò ọ́ ògo rẹ̀ sì farahàn lóríi rẹ.
3
Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
4
“Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ: Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn, àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá.
5
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fó yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá.
6
Ọ̀wọ́ ràkunmí yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ràkunmí Mídíánì àti Ẹfà. Àti gbogbo wọn létí Ṣèbà yóò wá, wọn yóò mú Góòlù àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn OLÚWA.
7
Gbogbo agbo ẹran Kédárì ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nébáíótì yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹ́ḿpìlì ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.
8
“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kùrukùru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?
9
Lótìítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn, pẹ̀lú fàdákà àti góòlùu wọn, fún ti ọlá OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.
10
“Àwọn àjèjì yóò tún ògiriì rẹ mọ àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́, ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.
11
Gbogbo ẹnu bodè rẹ ni yóò wà ní sísí sílẹ̀, a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè wá tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.
12
Nítorí pé orílẹ̀ èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun; pátapáta ni yóò sì dahoro.
13
“Ògo Lẹ́bánónì yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, igi páínì, fírì àti ṣípírẹ́sì papọ̀, láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi; àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
14
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ; gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú OLÚWA, Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
15
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran.
16
Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdè a ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi OLÚWA, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.
17
Dípò búróǹsì, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, àti fàdákà dípò irun Dípò igi yóò mú búróńsì wá, àti irun dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe gómínà rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
18
A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́, tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà àti àwọn ẹnu bodè rẹ ní ìyìn.
19
Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànsán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí OLÚWA ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
20
Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; OLÚWA ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.
21
Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni èhù tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọlá ńlá mi hàn.
22
Èyí tí ó kéré jù nínú un yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan, èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀ èdè ńlá. Èmi ni OLÚWA; ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
← Chapter 59
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 61 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→