bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 45
Isaiah 45
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 44
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 46 →
1
Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kírúsì, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀ èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti sí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
2
Èmi yóò lọ ṣíwájú rẹ èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹṣẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
3
Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó farasin, Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
4
Nítorí Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi àti Ísírẹ́lì ẹni tí mo yàn Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
5
Èmi ni OLÚWA, àti pé kò sí ẹlòmìíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6
tí o fi jẹ́ pé láti ìlà oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
7
Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù; Èmi OLÚWA ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8
“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; jẹ́ kí àwọ̀sánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbàgàdà, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; Èmi OLÚWA ni ó ti dá a.
9
“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrin àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, ‘Òun kò ní ọwọ́?’
10
Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11
“Ohun tí OLÚWA wí nìyìí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀: Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12
Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọnìyàn sóríi rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run mo sì kó àwọn agbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta
13
Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi: Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”
14
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì, àti àwọn Ṣábíáṣì— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15
Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Ísírẹ́lì
16
Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
17
Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni a ó gbàlà láti ọwọ́ OLÚWA Pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójú tì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun.
18
Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé: “Èmi ni OLÚWA, kò sì sí ẹlòmìíràn.
19
Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó farasin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn; Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jákọ́bù pé ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi OLÚWA sọ òtítọ́; Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
20
“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìṣáǹṣá láti àwọn ọrílẹ̀ èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
21
J ẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, OLÚWA? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmìíràn àfi èmi.
22
“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì sí ẹlòmìíràn.
23
Nípa èmi tìkálára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lúu gbogbo ipá mi ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́: Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24
Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú OLÚWA nìkan ni òdodo àti agbára wà.’ ” Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn.
25
Ṣùgbọ́n nínú OLÚWA gbogbo àwọn ìran Ísírẹ́lì ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
← Chapter 44
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 46 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→