bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 23
Isaiah 23
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 24 →
1
Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè: Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì! Nítorí a ti pa Tírè run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.
2
Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì, ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀.
3
Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wá ìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀ èdè.
4
Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọ àní ìwọ ilé-ààbò ti òkun, nítorí òkun ti sọ̀rọ̀: “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
5
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Éjíbítì, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tírè.
6
Kọjá wá sí Táṣíṣì; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
7
Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyáa yín, ògbólógbòò ìlú náà, èyí tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
8
Ta ló gbérò èyí sí Tírè, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládé tí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?
9
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀.
10
Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò Náì, Ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
11
OLÚWA ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíà pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
12
Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́” ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
13
Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì, àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìí Àwọn Ásíríà ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
14
Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
15
Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
16
“Mú hápù kan, rìn kọjá láàrin ìlú, Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu hápù rẹ dáadáa, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántíi rẹ.”
17
Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, OLÚWA yóò bá Tírè jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.
18
Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èree rẹ̀ àti owó iṣẹ́ẹ rẹ̀ ni a ó yà ṣọ́tọ̀ fún OLÚWA; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú OLÚWA, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 24 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→