bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 7
Isaiah 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 8 →
1
Nígbà tí Áhásì ọmọ Jótamù ọmọ Hùṣáyà jẹ́ ọba Júdà, ọba Résínì ti Árámù àti Pẹ́kà ọmọ Rẹ̀málíà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá láti bá Jérúsálẹ́mù jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.
2
Báyìí, a sọ fún ilé Dáfídì pé, “Árámù mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfáímù”; fún ìdí èyí, ọkàn Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
3
Lẹ́yìn èyí, OLÚWA sọ fún Àìṣáyà pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣéárì-Jáṣúbù láti pàdé Áhásì ní ìpẹ̀kun ìṣàn-omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
4
Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.
5
Árámù, Éfáímù àti Rèmálíà ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,
6
“Jẹ́ kí a kọlu Júdà; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrin ara wa, kí a sì fi ọmọ Tábẹ́lì jọba lóríi rẹ̀.”
7
Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí: “ ‘Èyí kò ní wáyé Èyí kò le ṣẹlẹ̀,
8
nítorí Dámásíkù ni orí Árámù, orí Dámásíkù sì ni Résínì. Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́ta Éfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
9
Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù, ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà.’ ”
10
Bákan náà OLÚWA tún bá Áhásì sọ̀rọ̀,
11
“Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jìn jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ”
12
Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán OLÚWA wò.”
13
Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí?
14
Nítorí náà, OLÚWA fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.
15
Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.
16
Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
17
OLÚWA yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá.”
18
Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Éjíbítì wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Áṣíríà.
19
Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.
20
Ní ọjọ́ náà, OLÚWA yóò lo abẹfẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò, ọba Ásíríà, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.
21
Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.
22
Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàsì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàsì àti oyin.
23
Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ti ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.
24
Àwọn ènìyàn yóò máa lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà.
25
Fún àwọn òkè tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ ṣíbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń tú agbo ẹran sí, àti ibi tí àwọn àgùntàn ti ń sáré.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66