bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 43
Isaiah 43
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 42
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 44 →
1
Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí OLÚWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bù ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ tèmi ni ìwọ ṣe.
2
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3
Nítorí Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ, Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.
4
Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.
5
Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ àti fún gúṣù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7
ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
8
Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9
Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀. Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fi hàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10
“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi.
11
Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLÚWA, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12
Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13
Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
14
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì; “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Bábílónì nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15
Èmi ni OLÚWA, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”
16
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun, ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,
17
ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:
18
“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19
Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20
Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá, láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21
àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22
“Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, Ìwọ Jákọ́bù, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì mi Ìwọ Ísírẹ́lì.
23
Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ. Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhóró tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24
Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí. Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín.
25
“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedédé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26
Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn.
27
Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀; àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28
Nítorí náà, èmi yóò dójú ti àwọn ẹni àyẹ́sí inú tẹ́ḿpìlìi yín, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú ìparun bá Jákọ́bù àti ìtìjú bá Ísírẹ́lì.
← Chapter 42
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 44 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
Recommended Reading
Commentary
Isaiah Commentaries
→
Devotional
Isaiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→