bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 54
Isaiah 54
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 53
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 55 →
1
“Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni OLÚWA wí.
2
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró; sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpo rẹ lágbára sí i.
3
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì; ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
4
“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwee rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìwà-rópó rẹ mọ́.
5
Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ; a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
6
OLÚWA yóò pè ọ́ padà à fi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá já kulẹ̀” ni OLÚWA wí.
7
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá.
8
Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni OLÚWA Olùdáǹdè rẹ wí.
9
“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Núà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10
Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì sí àwọn òkè kékeré nídìí, Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni OLÚWA, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.
11
Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri tí a kò sì tù nínú, Èmi yóò fi òkúta tìróò kọ́ ọ àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú sáfírésì.
12
Èmi yóò fi rúbísì ṣe odiì rẹ, àwọn ẹnu ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
13
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni OLÚWA yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
14
Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ Ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun Ìpayà la ó mú kúrò pátapáta; kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
15
Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ọ̀ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
16
“Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú di èjò-iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
17
Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan, ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni OLÚWA wí.
← Chapter 53
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 55 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66