bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 2
Isaiah 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 3 →
1
Èyí ni ohun tí Àìsáyà ọmọ Ámósì rí nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù:
2
Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹ́ḿpìlì OLÚWA ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kékeré lọ, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì máa ṣàn sínú un rẹ̀.
3
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn ó si sọ pé “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ sí òkè OLÚWA, sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Síhónì wá, àti ọ̀rọ̀ OLÚWA láti Jérúsálẹ́mù wá.
4
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀ wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀ èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀ èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
5
Wá, ẹ̀yìn ará ilée Jákọ́bù ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ OLÚWA. Ọjọ́ OLÚWA.
6
Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jákọ́bù. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ó ti ìlà oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Fílístínì wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà
7
Ilẹ̀ wọ́n kún fún fàdákà àti wúrà ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
8
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tikálára wọn ti ṣe.
9
Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjìn wọ́n.
10
Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú èrùpẹ kúrò nínú ìpayà OLÚWA, àti ògo ọlá ńlá rẹ̀!
11
Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, OLÚWA nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
12
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan nípamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀sílẹ̀),
13
nítorí gbogbo igi kedari Lẹ́bánónì, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Báṣánì,
14
nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéé kèè kéé,
15
fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò,
16
fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17
Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, OLÚWA nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18
gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.
19
Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà OLÚWA àti ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20
Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò má a sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán,
21
Wọn yóò ṣálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà OLÚWA àti ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
22
Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́ èmí ẹni tó wà ní imú un rẹ̀ kín ni ó jámọ́?
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66