bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Isaiah 57
Isaiah 57
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 56
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 58 →
1
Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀; a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì sí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
2
Gbogbo àwọn tí ń rìn déédéé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn lókùú.
3
“Ṣùgbọ́n ìwọ wá níhìnín, ìwọ ọmọ àjẹ́ yìí, ìwọ ìran panṣágà àti aṣẹ́wó!
4
Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í haá ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìràn àwọn òpùrọ́?
5
Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrin igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rúbọ nínú kòtò jínjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
6
Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídán wọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín; àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ oníhóró. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?
7
Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
8
Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀, ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.
9
Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífì ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10
Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.
11
“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
12
Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
13
Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
14
A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15
Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16
Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú ṣá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ọmọnìyàn tí mo ti dá.
17
Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínú ṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18
Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19
ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Ísírẹ́lì. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni OLÚWA wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20
Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21
“Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”
← Chapter 56
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 58 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66