bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 1
Jeremiah 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 2 →
1
Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà ọmọ Hílíkíyà ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Ánátótì ní gbígbé ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.
2
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Jòṣáyà ọmọ Ámónì Ọba Júdà,
3
Àti títí dé àsìkò Jéhóákímù ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, títí dé oṣù kaàrún ọdún kọkànlá Ṣedekáyà ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, nígbà tí àwọn ará Jérúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn.
4
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá, wí pé,
5
Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀ èdè.
6
Mo sọ pé Háà! OLÚWA tí ó pọ̀ ní ipá, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.
7
OLÚWA sọ fún mi pé, má ṣe sọ pé ọmọdé lásán ni mí. O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.
8
OLÚWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.
9
OLÚWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsìnyìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ
10
Wòó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti má a kọ́, àti láti máa gbìn.
11
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ mí wá wí pé “Kí ni o rí Jeremáyà?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi álímọ́ńdi”
12
OLÚWA sì wí fún mi pé, “ó ti rí i bí ó se yẹ, torí pé mo ti ń sọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúsẹ.”
13
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ́kèjì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.
14
OLÚWA, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti da ìdààmú sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà.
15
Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè àríwá níjà,” ni OLÚWA wí. Àwọn Ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú-ọ̀nà à bá wọlé Jérúsálẹ́mù. Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Júdà.
16
Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀, nípa rírúbọ sí Ọlọ́run mìíràn àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.
17
“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pa lásẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọn dẹ́rù bà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn.
18
Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
19
Wọn yóò dojú ìjà kọọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni OLÚWA wí.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52