bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 3
Jeremiah 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 4 →
1
“Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá? Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí? Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́, ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?” ni OLÚWA wí.
2
“Gbé ojú rẹ sí ibi gíga aláìléso kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò ti fi agbára mú ọ? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, o jókòó bí i àwọn alárìnkiri nínú ihà. O ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà panṣágà àti ìwà búburú rẹ.
3
Nítorí náà, a ti fa ọ̀wàrà òjò sẹ́yìn, kò sì sí òjò àrọ̀kúrò. Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.
4
Ǹjẹ́ ìwọ kò há a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5
Ìwọ yóò ha máa bínú títí? Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’ Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ń ṣe gbogbo ibi tí o le ṣe.”
6
Ní àkókò ìjọba Jòsáyà Ọba, OLÚWA wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.
7
Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Júdà aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.
8
Mo fún Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Ṣíbẹ̀ mo rí pé Júdà tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.
9
Nítorí ìwà èérí Ísírẹ́lì kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi.
10
Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Júdà arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olótìtọ́,” ni OLÚWA wí.
11
OLÚWA wí fún mi pé, “Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Júdà tí ó ní Ìgbàgbọ́ lọ.
12
Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “ ‘Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́,’ ni OLÚWA wí. ‘Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni OLÚWA wí.
13
Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, o ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ, o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi, tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,’ ” ni OLÚWA wí.
14
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni OLÚWA wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì.
15
Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.
16
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni OLÚWA wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí OLÚWA’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.
17
Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jérúsálẹ́mù ní ìtẹ́ OLÚWA gbogbo orílẹ̀ èdè yóò péjọ sí Jérúsálẹ́mù láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ OLÚWA, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle burúkú wọn mọ́.
18
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Júdà yóò darapọ̀ mọ́ ilé Ísírẹ́lì. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.
19
“Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
20
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Ísírẹ́lì” ni OLÚWA wí.
21
A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run wọn.
22
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni OLÚWA Ọlọ́run wa.
23
Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrùkèrudò tí ó wà ní àwọn orí òkè kékèké àti àwọn òkè gíga; Nítòótọ́, nínú OLÚWA Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.
24
Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti pa èso iṣẹ́ àwọn baba wa, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
25
Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run wa.”
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52