bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 6
Jeremiah 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 7 →
1
“Ẹ̀yin ènìyàn Bẹ́ńjámínì, sá síbi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jérúsálẹ́mù, Ẹ fọn fèrè ní Tékóà! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Bẹti-Ákérémù! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára.
2
Èmi yóò pa ọmọbìnrin Síónì run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.
3
Olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbógun tì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”
4
“Múra sílẹ̀ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọ lù ú ní ìgbà ọ̀sán! Àmọ́ ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
5
Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọ lù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”
6
Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jérúsálẹ́mù ká. A gbọdọ̀ fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè yìí nítorí pé ó kún fún ìrẹ́nijẹ.
7
Gẹ́gẹ́ bí kàǹga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún dún padà nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
8
Ìwọ Jérúsálẹ́mù, gba ìkìlọ̀ kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.”
9
Èyí ni ohun tí OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pesẹ́ ìyókù Ísírẹ́lì ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èṣo àjàrà jọ.”
10
Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ OLÚWA, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11
Èmi kún fún ìbínú OLÚWA, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kóra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni OLÚWA wí.
13
“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn.
14
Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà’, nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15
Ojú há a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní ooru ìtìjú Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrin àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá fìyà jẹ” wọ́n ni OLÚWA wí.
16
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò, ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọ inú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rin nínú rẹ.’
17
Èmi yan olùsọ́ fún un yín, mo sì wí pé: ‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’
18
Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè kíyèsí, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí wọn.
19
Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, eṣo ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.
20
Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti ṣébà wá, tàbí eso dáradára láti ilẹ̀ jínjìn réré? Ọrẹ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹbọ yín kò sì wù mí.”
21
Nítorí náà, èyi ni ohun tí OLÚWA wí: “Èmi yóò gbé ohun ìdènà ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn bàbá àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”
22
Èyí ni OLÚWA wí: “Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá, a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti òpin ayé wá.
23
Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú wọ́n ń hó bí omi òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹsin wọn lọ; wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”
24
Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí ìrora bí obìnrin tí í rọbí.
25
Má ṣe jáde lọ sí orí i pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo.
26
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé asọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín, kanṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.
27
“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.
28
Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀ òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.
29
Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkán, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán; a ko si ya ènìyàn búburú kúrò.
30
A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀ sílẹ̀, nítorí OLÚWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52