bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 5
Jeremiah 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 6 →
1
“Lọ sókè àti sódò àwọn òpó Jérúsálẹ́mù Wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo, N ó dárí jìn ìlú yìí.
2
Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí OLÚWA ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.”
3
OLÚWA, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́ Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n. Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.
4
Èmi sì rò pé, “talákà ni àwọn yìí wọn kò lóye nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà OLÚWA, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
5
Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà OLÚWA àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.” Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè.
6
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.
7
“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.
8
Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sunkún sí aya arákùnrin wọn.
9
Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí?” ni OLÚWA wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí?
10
“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti OLÚWA.
11
Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti jẹ́ aláìsòdodo sí mi,” ni OLÚWA wí.
12
Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ OLÚWA; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
13
Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”
14
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.
15
Áà, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè láti ọ̀nà jínjìn dìde sí i yín Orílẹ̀ èdè ìgbàanì àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.
16
Àpò ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a sí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.
17
Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.”
18
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni OLÚWA wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátapáta.
19
Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin Ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsìnyìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe ti yín.’
20
“Kéde èyí fún ilé Jákọ́bù, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà.
21
Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aláìlóye àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́ran.
22
Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni OLÚWA wí. “Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
23
Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀, wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24
Wọn kò sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédéé.’
25
Àìṣedéedée yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
26
“Láàrin ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
27
Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn. Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
28
Wọ́n sanra wọ́n sì dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
29
Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni OLÚWA wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀ èdè bí èyí bí?
30
“Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
31
Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn, àwọn ènìyàn mi sì nífẹ̀ẹ́ sí èyí, kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52