bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 12
Jeremiah 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 13 →
1
OLÚWA, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédéé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìsòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?
2
Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀, wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso. Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn, o jìnnà sí ọkàn wọn.
3
Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní OLÚWA, o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò. Wò ó, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa. Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
4
Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà, tí gbogbo ewéko ìgbẹ́ sì ń rọ? Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀. Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé, “Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ síwa.”
5
Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́sẹ̀ díje, tí àárẹ̀ sì mú ọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje? Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà, báwo ni ìwọ ó ṣe ṣe nínú ihà Jọ́dánì?
6
Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé— ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ Wọ́n ti hó lé ọ lórí; Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa.
7
Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, màá fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
8
Ìní mi ti dàbí kìnnìún nínú igbó sí mi Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
9
Ìní kò ha ti dàbí ẹyẹ kanna-kánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì kọ tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Lọ kí o lọ ṣe àkójọ gbogbo àwọn ẹranko búburú, kó wọn wá láti wá parun.
10
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́ àgùntàn ni yóò sì ba oko àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; Wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
11
A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.
12
Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà OLÚWA yóò pa láti ìkángun kìn-ín-ní dé ìkángun ìkejì ilẹ̀ náà; kò sí ẹni tí yóò yè.
13
Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tìyín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná OLÚWA.
14
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Júdà tu kúrò ní àárin wọn.
15
Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.
16
Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘OLÚWA ń bẹ,’ gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé, OLÚWA wà a kọ́ ènìyàn mi láti fi Báálì búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrin ènìyàn mi.
17
Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kan kò bá tẹ́tí. Èmi yóò fà á tu pátapáta n ó sì run wọ́n,” ni OLÚWA wí.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52