bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 23
Jeremiah 23
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 24 →
1
“Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni OLÚWA wí.
2
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ ní ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín níyà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni OLÚWA wí.
3
“Èmi OLÚWA tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi.
4
Èmi ó wá olùṣọ́ àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni OLÚWA wí.
5
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dáfídì, Ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
6
Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Júdà là, Ísírẹ́lì yóò sì máa gbé ní aláìléwu Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: OLÚWA Òdodo wa.
7
“Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú OLÚWA wà láàyè tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.’
8
Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú OLÚWA ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”
9
Nípa ti àwọn wòlíì èké: Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí OLÚWA àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
10
Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn nítorí ẹ̀gún ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn kóríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.
11
“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwàbí Ọlọ́run; kódà nínú Tẹ́ḿpìlì mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni OLÚWA wí.
12
“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n níyà,” ni OLÚWA wí.
13
“Láàrin àwọn wòlíì Saáríà, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá: Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Báálì wọ́n sì mú Ísírẹ́lì ènìyàn mi sìnà.
14
Àti láàrin àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù, èmi ti rí ohun búburú: Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sódómù níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.”
15
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”
16
Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹmá ṣe fi etí sí àṣọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu OLÚWA.
17
Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘OLÚWA ti wí pé: Ẹ ó ní àlàáfíà,’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’
18
Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ OLÚWA láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?
19
Wò ó, afẹ́fẹ́ OLÚWA yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú àfẹ́yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú.
20
Ìbínú OLÚWA kì yóò yẹ̀ títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ, ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.
21
Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn. Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀,
22
Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi, wọn ì bá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi. Wọn ì bá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ènìyàn wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà àti ìṣe búburú wọn.
23
“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?” ni OLÚWA wí, “kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jínjìn.
24
Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni OLÚWA wí. “Ǹjẹ́ èmi kò há a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni OLÚWA wí.
25
“Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’
26
Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn?
27
Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.
28
Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni OLÚWA wí.
29
“Ọ̀rọ̀ mi kò há a dàbí iná?” ni OLÚWA wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?
30
“Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” OLÚWA wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn.
31
Bẹ́ẹ̀,” ni OLÚWA wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ wí pé, ‘OLÚWA wí.’
32
Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni OLÚWA wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi sìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni OLÚWA wí.
33
“Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni OLÚWA wí.’
34
Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.
35
Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀: ‘Kí ni ìdáhùn OLÚWA?’ tàbí ‘Kíni ohun tí OLÚWA sọ?’
36
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ OLÚWA’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára alààyè padà.
37
Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn OLÚWA sí ọ́?’ tàbí ‘Kí ni ohun tí OLÚWA bá ọ sọ?’
38
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA,’ èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: Ó ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe gbà á, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA.’
39
Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín.
40
Èmi yóò sì mú ìtìjú ayérayé wá sí orí yín, ìtìjú tí kò ní ní ìgbàgbé.”
← Chapter 22
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 24 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52