bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 15
Jeremiah 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 16 →
1
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún mi pé: “Kódà kí Mósè àti Sámúẹ́lì dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!
2
Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbékùn mọ́ sí ìgbékùn.’
3
“Èmi yóò rán oríṣìí ìparun mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni OLÚWA wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.
4
N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Mánásè ọmọ Heṣekáyà Ọba àwọn Júdà ṣe ní Jérúsálẹ́mù.
5
“Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù? Ta ni yóò dárò rẹ? Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
6
O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni OLÚWA wí “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́ lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run; Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
7
Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ Èmi yóò fi atẹ fẹ́ wọn sí ẹnu ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìsọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tíì yí padà kúrò lọ́nà wọn.
8
Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn òkun lọ. Ní ọjọ́kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójìjì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
9
Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni OLÚWA wí.
10
Áà Ó ṣe tí ìyá mi bí mi: ọkùnrin tí gbogbo ìtẹ́ tiraka tí wọ́n sì bá jà, èmi kò wín ni, bẹ́ẹ̀ ni èmi ò yá lọ́wọ́ ẹni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11
OLÚWA sọ pé, “Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó. Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ipọ́njú.
12
“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ?
13
Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nkànkan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀ èdè rẹ.
14
Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15
Ó yé ọ, ìwọ OLÚWA rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16
Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí Ìwọ OLÚWA Ọlọ́run alágbára.
17
Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrin àwọn ẹlẹ́gàn. Má ṣe bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18
È é ṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi ń nira tí kò sì ṣe é wòsàn? Ṣe ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19
Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí: “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20
Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni OLÚWA wí.
21
“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52