bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 28
Jeremiah 28
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 29 →
1
Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé OLÚWA tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn:
2
“Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà Ọba Bábílónì rọrùn.
3
Láàrin ọdún méjì, mà á mú gbogbo ohun èlò tí Ọba Nebukadinésárì; Ọba Bábílónì kó kúrò ní ilé OLÚWA tí ó sì kó lọ sí Bábílónì padà wá.
4
Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì,’ èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn.’ ”
5
Wòlíì Jeremáyà fún wòlíì Hananáyà lésì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé OLÚWA.
6
Ó sọ wí pé, “Àmín! Kí OLÚWA ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí OLÚWA ó mú àwíṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun èlò ilé OLÚWA àti gbogbo àwọn aṣàtìpó padà sí ilẹ̀ Bábílónì.
7
Nísinsìnyìí, tẹ́tí sí àwọn ohun tí mo sọ fún gbígbọ́ àti fún gbígbọ́ gbogbo ènìyàn.
8
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè.
9
Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olótítọ́ tí OLÚWA rán, tí àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”
10
Wòlíì Hananáyà gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì fọ́ ọ.
11
Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ‘Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì.’ ” Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
12
Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé:
13
“Lọ sọ fún Hananáyà, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní àyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.
14
Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”
15
Wòlíì Jeremáyà sọ fún Hananáyà wòlíì pé, “Tẹ́tí, Hananáyà! OLÚWA ti rán ọ, síbẹ̀, o rọ orílẹ̀ èdè yìí láti gba irọ́ gbọ́.
16
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí OLÚWA.’ ”
17
Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananáyà wòlíì kú.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52