bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 9
Jeremiah 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 10 →
1
Áà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé Èmi yóò sì sunkún tọ̀sán tòru nítorí pípa àwọn ènìyàn mi.
2
Áà! èmi ìbá ní ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò ní ihà kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn: nítorí gbogbo wọn jẹ́ pańṣágà àjọ aláìsòótọ́ ènìyàn ni wọ́n.
3
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òótọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn, wọn kò sì náání mi, ní OLÚWA wí.
4
Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ nítorí pé oníkálukú arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálukú ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.
5
Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì sí ẹni tó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀
6
Ó ń gbé ní àárin ẹ̀tàn wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn, ni OLÚWA wí.
7
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?
8
Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró ó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálukú sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládúgbò rẹ̀; ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.
9
Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni OLÚWA wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí?”
10
Èmi yóò sì sunkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkún ìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.
11
“Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtì àlàpà àti ìhò àwọn ìkokò. Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahoro tí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”
12
Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni OLÚWA ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
13
OLÚWA sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
14
Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Báálì gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.
15
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
16
Èmi yóò sì tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
17
Èyí sì ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: “Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá; sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
18
Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi ṣàn fún omijé tí omi yóò sì máa ṣàn àwọn ìpéǹpéjú wa
19
A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Síónì: ‘Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”
20
Nísínsìnyìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA. Sí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
21
Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọ́kùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.
22
Sọ pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”
23
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọgbọ́n yangàn nítorí ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
24
Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé òun ní òye, òun sì mọ̀mí wí pé, Èmi ni OLÚWA tí ń ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo ní ayé nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” OLÚWA wí.
25
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.
26
Éjíbítì, Júdà, Édómù, Ámónì, Móábù àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jínjìn réré ní ihà. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52