bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 7
Jeremiah 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 8 →
1
Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jérémáyà wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA.
2
“Dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí: “ ‘Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin OLÚWA.
3
Èyi ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí.
4
Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni ilé Tẹ́ḿpìlì OLÚWA ilé Tẹ́ḿpìlì OLÚWA, ilé Tẹ́ḿpìlì OLÚWA!”
5
Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti ìṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́.
6
Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín.
7
Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.
8
Ẹ wò ó, Ẹ̀ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.
9
“ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ se pánṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Báálì, kí ẹ sì tọ Ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ.
10
Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” sé yíyè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìnira wọ̀nyí bí?
11
Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́sà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni OLÚWA wí.
12
“ ‘Ẹ lọ nísinsìn yìí sí ṣílò níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Ísírẹ́lì tí í ṣe ènìyàn mi.
13
Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni OLÚWA wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn
14
Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.
15
Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Éfúráímù.’
16
“Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ.
17
Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?
18
Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná síi, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn Ọlọ́run àjòjì láti mú mi bínú sókè.
19
Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni OLÚWA wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?
20
“ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èṣo orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.
21
“ ‘Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: Tẹ̀ṣíwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yóòkù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín.
22
Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba-ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán.
23
Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Má a rìn ní ojú ọ̀nà tí mo paláṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín.
24
Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetí sílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀ṣíwájú wọ́n ń rẹ̀yìn.
25
Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Éjíbítì títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín.
26
Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’
27
“Nígbà tí wọ́n bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn.
28
Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀ èdè tí kò gbọ́ ti OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn
29
ṣe irun yín kí ẹ sì dàanù, pohùnréré ẹkún lorí òkè aṣálẹ̀, nítorí OLÚWA ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.
30
“ ‘Àwọn ènìyàn Júdà ti ṣe búburú lójú mi, ni OLÚWA wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́.
31
Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tófẹ́tì ní àfonífojì Beni Hínómí láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò paláṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi.
32
Nítorí náà kíyèsára ọjọ́-ń-bọ̀, ni OLÚWA wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Táfétì tàbí àfonífojì ti Beni Hínómì; àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tófẹ́tì títí kò fi ní sí àyè mọ́
33
Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
34
Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọ tìyàwó ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52