bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 41
Jeremiah 41
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 40
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 42 →
1
Ní oṣù keje Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ọmọkùnrin Élísámà ti ìdílé Ọba, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ọba, tọ Jedaláyà ọmọ Áhíkámù ti Mísípà wá pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n ń jẹun papọ̀.
2
Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Jedaláyà ọmọ Áhíkámù, ọmọ Sáfánì pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí ilẹ̀ náà.
3
Íṣímáẹ́lì sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Jedaláyà ní Mísípà, àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.
4
Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Jedaláyà kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀
5
Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣékémù, Ṣílò àti Saaríà, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n sá ara wọn lọ́gbẹ́ wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé OLÚWA.
6
Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà jáde kúrò láti Mísípà láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sunkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹwá sọ́dọ̀ Jedaláyà ọmọkùnrin Álíkámù.”
7
Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nètanáyà àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ìhò kan.
8
Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Ísímáẹ́lì pé, “Má se pa wá! Àwa ní ọkà àti Bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yóòkù.
9
Nísinsìn yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Jedaláyà sí ni Ọba Aṣa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí Ọba Báṣì ti Ísírẹ́lì. Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.
10
Ísímáẹ́lì sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mísípà nígbèkùn, ọmọbìnrin Ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tó kù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusarádánì balógun àwọn ẹ̀sọ́ ti fi yan Gédáláyà ọmọkùnrin Álíkámù ṣe olórí. Isímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ámónì.
11
Nígbà tí Johánánì ọmọkùnrin Kárè àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà ti ṣe.
12
Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gídéónì.
13
Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Ísímáẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀.
14
Gbogbo àwọn ènìyàn tí Ísímáẹ́lì ti kó ní ìgbékùn ní Mísípà yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Jóhánánì ọmọ Káréà.
15
Ṣùgbọ́n Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Jóhánánì, wọ́n sì sálọ sí Ámónì.
16
Lẹ́yìn náà Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mísípà; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gédáláyà ọmọ Álíkámù. Àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gíbíónì.
17
Wọ́n sì dúró ní Gérútì Kímámù ní ẹ̀bá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nínú ìrìnàjò wọn sí Éjíbítì.
18
Láti gba àwọn Bábílónì sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà ti pa Jedaláyà ọmọ Álíkámù èyí tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómínà lórí ilẹ̀ náà.”
← Chapter 40
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 42 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52