bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 20
Jeremiah 20
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 21 →
1
Ní ìgbà tí àlùfáà Pásúrì ọmọkùnrin Ímímérì olórí àwọn ìjòyè Tẹ́ḿpìlì OLÚWA gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí.
2
Ó mú kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu ọ̀nà ti Bẹ́ńjámínì ní Tẹ́ḿpìlì OLÚWA.
3
Ní ọjọ́ kejì tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremáyà sì sọ fún un wí pé, “orúkọ OLÚWA kì í ṣe Páṣúrì fún ọ bí kò ṣe ohun ẹ̀rù.
4
Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Júdà lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Bábílónì tàbí kí ó pa wọ́n.
5
Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀ta wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá Ọba Júdà. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Bábílónì.
6
Àti ìwọ Páṣúrì, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Bábílónì. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”
7
OLÚWA, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
8
Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLÚWA ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
9
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi tí a sé nínú egungun mi Agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
10
Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, Bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”
11
Ṣùgbọ́n OLÚWA wà pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí jagunjagun alágbára. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
12
OLÚWA alágbára, ìwọ tí ó ń dán olódodo pípé wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀yà fínní-fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.
13
Kọrin sí OLÚWA! Fi ìyìn fún OLÚWA! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.
14
Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
15
Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”
16
Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí OLÚWA gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáànú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán.
17
Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.
18
Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52