bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 2
Jeremiah 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 3 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Lọ kéde sí etí ìgbọ́ àwọn Jérúsálẹ́mù: “ ‘Mo rántí ìfarasìn ìgbà èwe rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi bí i wúndíá àti bí o ṣe tẹ̀lé mi nínú aṣálẹ̀ àti nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
3
Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA, àkọ́kọ́ èṣo ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ìpọ́njú yóò dé bá wọn,’ ” bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí.
4
Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bù àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì.
5
Báyìí ni OLÚWA wí: “Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi? Tí wọ́n fi jìnnà sími? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kan àwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ.
6
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni OLÚWA wà tí ó mú wọn, jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wa la ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọn aṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé?’
7
Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sì ba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọn ohun ogún mi di ohun ìríra.
8
Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni OLÚWA wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olórí wọn sì gbógun sí mi, àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà yẹpẹrẹ.
9
“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi,” ni OLÚWA wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10
Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí o sì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sì wò ó dáradára, wò ó kí ẹ sì wò ó bí irú nǹkan báyìí bá wà níbẹ̀ rí?
11
Orílẹ̀ èdè kan há á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọn kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run) àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12
Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni OLÚWA wí.
13
“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀, méjì Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti wọ àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.
14
Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí? Kí ló há a dé tí ó fi di ìkógun?
15
Àwọn kìnnìún ké ramúramú wọ́n sì ń bú mọ́ wọn wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.
16
Bákan náà, àwọn ọkùnrin Mémífísì àti Táfánésì wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17
Ẹ̀yin kò há a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18
Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Éjíbítì láti lọ mu omi ní Síhórì? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Àsíríà láti lọ mu omi ni odò Yúfúrátè náà
19
Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín Ìpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọ ogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,” ni OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí.
20
“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
21
Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá, Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
22
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ àbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi,” ni OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí.
23
“Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́; Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀ tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún.
24
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihà tí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí í lé e má ṣe dára wọn lágara nítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
25
Má ṣe sáré títí ẹṣẹ̀ yín yóò fi wà ní ìhòòhò, tí ahọ́n yín yóò sì gbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Kò nílò! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, èmi yóò sì lépa wọn lọ.’
26
“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójú ti olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ilé Ísírẹ́lì yóò gba, àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
27
Wọn sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi,’ àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’ wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi ṣíbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
28
Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run (kékeré) tí ẹ ṣe fúnra yín há a wà? Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà.
29
“Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni OLÚWA wí.
30
“Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí, idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.
31
“Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ OLÚWA: “Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùn kí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣe sọ wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’
32
Wúndíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, tàbí ìyàwó ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.
33
Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin tí ó tilẹ̀ burú yóò kẹ́kọ̀ọ́ láti àwọn ọ̀nà rẹ
34
Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn talákà aláìṣẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ká wọn níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé
35
Ṣíbẹ̀ nínú gbogbo èyí ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìsẹ̀ kò sì bínú sími.’ Èmi yóò ṣe ìdájọ́ mi lórí rẹ nítorí pé ìwọ sọ pé, ‘Èmi kò tí ìdẹ́sẹ̀.’
36
Kí ló dé tí o fi ń lọ káàkiri láti yí ọ̀nà rẹ padà? Éjíbítì yóò dójú tì ọ́ gẹ́gẹ́ bí i ti Ásíríà
37
Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ọwọ ìkáwọ́ lórí rẹ ní orí rẹ nítorí pé OLÚWA ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé, kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn wá.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52