bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 40
Jeremiah 40
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 39
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 41 →
1
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA lẹ́yìn tí Nebukadinésárì balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rámà. Ó rí Jeremáyà tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Bábílónì.
2
Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremáyà, ó sọ fún-un wí pé, “OLÚWA Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi.
3
Nísinsìn yìí, OLÚWA ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí OLÚWA, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
4
Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lémi kálọ sí Bábílónì, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, má ṣe wá. Wò ó, gbogbo orílẹ̀ èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”
5
Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremáyà pẹ̀yìn dà láti máa lọ, Nebusárádánì fikún un wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Jedaláyà ọmọ Álíkámù, ọmọ Sáfánì, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí olórí lórí ìlú Júdà, kí o sì máa gbé ní àárin àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá wù ọ́.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
6
Báyìí ni Jeremáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ní Mísípà, ó sì dúró tì í láàrin àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà.
7
Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀ èdè náà gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ talákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀
8
Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, Jóhánónì àti Jónátanì ọmọkùnrin ti Káréà, Séráyà ọmọkùnrin Tánúmétì tí í ṣe ọmọkùnrin Épáì ti Nétópátè àti Jásáníà ọmọkùnrin Mákétè àti àwọn ènìyàn wọn.
9
Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù, ọmọkùnrin ti Sáfánì ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn Bábílónì.” Ó sọ wí pé, “Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin Ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín.
10
Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mísípà láti ṣojú yín níwájú Bábílónì tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ ti gbà.”
11
Nígbà tí gbogbo àwọn Júdà ní Móábù, Ámónì, Édómù àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti fi ohun tó kù sílẹ̀ ní Júdà, àti pé ó ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ọmọkùnrin Sáfánì gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn.
12
Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Júdà sọ́dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà láti orílẹ̀ èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èṣo igi.
13
Jóhánánì ọmọkùnrin ti Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó kù ní orílẹ̀ èdè sì tọ Jedáláyà wá ní Mísípà.
14
Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Báálísì Ọba àwọn Ámónì ti rán Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Jedáláyà ọmọkùnrin ti Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́.
15
Nígbà náà ni Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Jedáláyà ní Mísípà pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Júdà sì parun?”
16
Ṣùgbọ́n Jedáláyà ọmọ Áhíkámù sọ fún Jóhánánì ọmọ Káréà pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Íṣímáẹ́lì kì í ṣe òtítọ́.”
← Chapter 39
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 41 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52