bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 26
Jeremiah 26
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 27 →
1
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Ọba Jehóáíkímù ọmọ Jòsáyà tí ń ṣe Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA:
2
“Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Dúró ní àgbàlà ilé OLÚWA, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé OLÚWA: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.
3
Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.
4
Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín.
5
Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀.
6
Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”
7
Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà tí ó sọ ní ilé OLÚWA.
8
Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí OLÚWA pa láṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!
9
Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLÚWA pé, ilé yìí yóò dàbí ṣílò, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremáyà nínú ilé OLÚWA.
10
Nígbà tí àwọn aláṣẹ Júdà gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin sí ilé OLÚWA, wọ́n sì mú àyè wọn, wọ́n jòkòó ní ẹnu ọ̀nà tuntun ilé OLÚWA.
11
Àwọn àlùfáà àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”
12
Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “OLÚWA rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.
13
Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. OLÚWA yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.
14
Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.
15
Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni OLÚWA ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”
16
Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ ogun.”
17
Lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà sì sún ṣíwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé,
18
“Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “ ‘A ó sì fa Síónì tu bí oko Jérúsálẹ́mù yóò di òkítì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’
19
“Ǹjẹ́ Heṣekáyà Ọba Júdà tàbí ẹnikẹ́ni ní Júdà pa á bí? Ǹjẹ́ Heṣekáyà kò bẹ̀rù OLÚWA tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ OLÚWA kò há a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”
20
(Bákan náà Úráyà ọmọ Ṣémáíà láti Kúríátì Jéárímù jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ OLÚWA. Ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremáyà ti ṣe.
21
Nígbà tí Ọba Jéhóíákímù àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Úráyà gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Éjíbítì.
22
Ọba Jéhóíákímù rán Elinátanì ọmọ Álíbórì lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.
23
Wọ́n sì mú Úráyà láti Éjíbítì lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Jéhóíákímù; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)
24
Áhíkámù ọmọ Sáfánì ń bẹ pẹ̀lú Jeremáyà, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 27 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52