bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jeremiah 31
Jeremiah 31
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 32 →
1
“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Ísírẹ́lì, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni OLÚWA wí.
2
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere OLÚWA ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì.”
3
OLÚWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
4
Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
5
Ẹ ó tún dá oko ní orí òkè Saáríà; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn.
6
Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Éfráímù wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì, ní ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run wa.’ ”
7
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘OLÚWA, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’
8
Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.
9
Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì, Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.
10
“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin orílẹ̀ èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn.’
11
Nítorí OLÚWA ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padà ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ
12
Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì; wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore OLÚWA. Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran. Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin, ìkorò kò ní bá wọn mọ́.
13
Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin. Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú. Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.
14
Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀; àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,” ni OLÚWA wí.
15
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà tí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò. Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀; kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”
16
Báyìí ni OLÚWA wí: “Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún àti ojú rẹ nínú omijé; nítorí a ó fi èrè sí isẹ́ rẹ,” ni OLÚWA wí. “Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.
17
Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,” ni OLÚWA wí. “Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.
18
“Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Éfúráímù wí pé, ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí. Ràmípadà, Èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni OLÚWA Ọlọ́run mi.
19
Lẹ́yìn tí mo ti ronúpìwàdà, èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, lẹ́yìn tí mo ti mọ̀, èmi lu àyà mi. Ojú tì mí, mo sì dààmú; nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’
20
Éfúráímù kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni OLÚWA wí.
21
“Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde, ṣe atọ́nà àmì, kíyèsí pópónà rélùwéè ojú ọ̀nà tí ó ń gbà. Yípadà ìwọ wúndíá Ísírẹ́lì, padà sí àwọn ìlú rẹ.
22
Ìwọ yóò ti sìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìsòótọ́ ọmọbìnrin; OLÚWA yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin yóò yí ọkùnrin kan ká.”
23
Báyìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan síi; wí pé, ‘OLÚWA bùkún fún ọ, ìwọ tí ń gbé nínú òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’
24
Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Júdà àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.
25
Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káànú lọ́rùn.”
26
Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
27
“Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.
28
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni OLÚWA wí.
29
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èṣo kíkan àti pé ẹyín kan àwọn ọmọdé.’
30
Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èṣo kíkan ni eyín yóò kan.
31
“Ìgbà kan ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí Èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.
32
Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni OLÚWA wí.
33
“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLÚWA wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ OLÚWA wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.
34
Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLÚWA,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títídé ẹni ńlá,” ni OLÚWA wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedédé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
35
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó OLÚWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.
36
“Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,” ni OLÚWA wí. “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀ èdè níwájú mi láéláé.”
37
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìṣàlẹ̀, ni èmi yóò kọ àwọn Ísírẹ́lì nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,” ni OLÚWA wí.
38
“Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hánánélì dé igun ẹnubodè.
39
Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Gárébì yóò sì lọ sí Góà.
40
Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì odò Kídírónì ní ìhà ìlà oòrùn títí dé igun ẹnubodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 32 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52