bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 11
Job 11
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 12 →
1
Ígbà náà ni Sófárì, ará Naamáa, dáhùn, ó sì wí pé:
2
“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀? A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3
Ṣé àmọ̀tàn rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí? Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4
Ìwọ sáà ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní óju rẹ.’
5
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ lára;
6
Kí ó sì fi àsírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ; Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
7
“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olodùmáarè dé bi?
8
Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe? Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
9
Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju òkun lọ.
10
“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà, tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11
Òun sáà mọ ènìyàn asán; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12
Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn yóò di ọlọgbọ́n, nígbà tí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ènìyàn.
13
“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14
Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.
15
Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láì ní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,
16
Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ.
17
Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18
Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19
Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ.
20
Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo; gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 12 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42