bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 15
Job 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 16 →
1
Ígbà náà ní Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé:
2
“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà oòrun kún ara rẹ̀ nínú?
3
Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
4
Ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí àdúrà lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
5
Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
6
Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi; àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí tì ọ́.
7
“Ìwọ ha íse ọkùnrin tí a kọ́ bi? Tabì a há dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
8
Ìwọ gburòó àsírí Ọlọ́run rí, tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
9
Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
10
Eléwú ogbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ.
11
Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ? Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
12
Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri, kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì.
13
Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?
14
“Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́? Àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
15
Kíyèsí i, òun (Ọlọ́run) kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀;
16
Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi.
17
“Èmi ó fihàn ọ́: gbọ́ ti èmi; Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18
tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn lati ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,
19
Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20
Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21
Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀; nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22
O kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápákan fún idà.
23
Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24
Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun.
25
Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè,
26
Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fi ìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú.
27
“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28
Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété, àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbé mọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.
29
Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30
Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ ní yóò máa kọjá lọ kúrò.
31
Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32
A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33
Yóò sì gbọ̀n àìpọ́n èṣo rẹ̀ dànù bí i àjàrà, yóò sì rẹ̀ ìyanna rẹ̀ nù bí i ti igi Ólífì.
34
Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35
Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèṣè ẹ̀tàn.”
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42