bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 8
Job 8
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 9 →
1
Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, sì dáhùn wí pé:
2
“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkán wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfú ńlá?
3
Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí, tàbí Olódùmárè a máa fi òtítọ́ sẹ̀ bí?
4
Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ sẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí àṣẹ wọn.
5
Bí ìwọ bá sì képe Ọlọ́run ní ìgbà àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmáarè.
6
Ìwọ ìbá mọ́, kí ó sì dúró sinṣsin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsìn yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
7
Ìpilẹsẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yin rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
8
“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsí ìwádìí àwọn baba wọn.
9
Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10
Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11
Koríko odò ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí èèsú ha lè dàgbà láìlómi?
12
Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò kee lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko mìíràn gbogbo hù dípò rẹ̀
13
Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, àbá àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14
Àbá ẹni tí a ó ké kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dà bí ilé aláǹtakùn.
15
Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́
16
Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17
Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18
Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà sẹ́ ẹ pé, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19
Kíyèsí i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti lati inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmìíràn yóò hù jáde wá.
20
“Kíyèsí i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà-búburú lọ́wọ́
21
títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀
22
ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó koríra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42