bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 9
Job 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 10 →
1
Jóòbù sì dáhùn ó sì wí pé:
2
“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́! Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3
Bí ó bá ṣe pé yóò bá jà, òun kì yóò lè dálóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rùn-ún ọ̀rọ̀.
4
Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òún; ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5
Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀
6
Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì
7
Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
8
Òun nìkanṣoṣo ni ó na ojú ọ̀run lọ, ti ó sì ń rìn lórí ìgbì òkun.
9
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Béárì, Óríónì àti Píléíádè àti yàrá púpọ̀ ti gúsù.
10
Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwàrí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye.
11
Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12
Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13
Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn oní rànlọ́wọ́ ti Ráhábù a sì tẹriba lábẹ́ rẹ̀.
14
“Kí ní ṣe tí èmi ò fi dá a lóhùn? Tí èmi kò fi máa fi ọ̀rọ̀ àwàwí mi ṣe àwsíyé fún-un?
15
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn, ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16
Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17
Nítorí pé òun yóò lọ̀ mi lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá ó sọ ọgbẹ́ mi di pupọ̀ láìnídìí.
18
Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19
Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ńi ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20
Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi óò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
21
“Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsí ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22
Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi se sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23
Bí ìjàǹbá bá pani lójijì, yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀.
24
Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25
“Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26
Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27
Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28
Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29
Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30
Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31
ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32
“Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34
Kí ẹnìkan ṣá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì se dáyà fò mí
35
Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dáré-ti mi, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42