bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 38
Job 38
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 37
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 39 →
1
Ígbà náà ní OLÚWA dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:
2
“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìní ìgbirò ṣu ìmọ̀ ní òkùnkùn?
3
Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dámi lóhùn.
4
“Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fi ìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
5
Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
6
Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
7
Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?
8
“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,
9
Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀,
10
Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tí mo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn,
11
Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
12
“Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀,
13
Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
14
Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
15
A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.
16
“Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17
A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?
18
Ìwọ mòye ibú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.
19
“Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
20
Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
21
Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.
22
“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ rí bí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí,
23
Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24
Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń ya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25
Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26
Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí;
27
Láti tẹ́ ilẹ̀ tútù, aṣálẹ̀ àti ẹgàn lọ́rùn láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
28
Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ikùn ìṣẹ ìrì?
29
Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
30
Omi di lile bí òkúta, ojú ibú ńlá sì dìlù pọ̀.
31
“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Píléyádè dáradára? Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Óríónù?
32
Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Másárótì jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Béárì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33
Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34
“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35
Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, àwa nìyí?
36
Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayé tàbí tí ó fi òye sínú ọkàn?
37
Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀ sánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
38
Nígbà tí erupẹ̀ di líle, àti ògúlùtú dípò?
39
“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún lọ́rùn,
40
Nígbà tí wọ́n bá ń mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
41
Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ìwọ, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?
← Chapter 37
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 39 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42