bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 28
Job 28
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 29 →
1
“Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
2
Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
3
Ènìyàn ni ó parí òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí òkúta òkùnkùn àti ti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
4
Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jìn sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹṣẹ̀ ènìyàn gbàgbé; wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
5
Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná.
6
Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
7
Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí;
8
Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
9
Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
10
Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
11
Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún —kún-ya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.
12
“Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?
13
Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14
Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi; omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.
15
A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16
A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbí òkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.
17
Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tó ẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.
18
A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì; iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.
19
Òkùta tópásì ti Kúsì kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
20
“Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21
A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22
Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
23
Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé
24
Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
25
Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ̀n omi.
26
Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
27
Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
28
Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, ‘Kíyè sí i ẹ̀rù OLÚWA èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.’ ”
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42