bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 31
Job 31
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 32 →
1
“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mu, èmi yó ha ṣe tẹjú mọ́ wúndíá?
2
Nítórí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmárè láti òkè ọ̀run wá.
3
Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀ àrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
4
Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣíṣẹ̀ mi?
5
“Bí ó bá ṣepé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;
6
(Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
7
Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,
8
Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.
9
“Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10
Ṣùgbọ́n kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11
Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀
12
Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
13
“Tí mo bá sì se àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
14
Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
15
Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
16
“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú talákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó di aláìríran,
17
Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
18
Nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
19
Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí talákà kan láìní ìbora;
20
Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípaṣẹ̀ irun àgùntàn mi;
21
Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22
Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ọkọ́ èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23
Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù-ńlá fún mi, àti nitorí Ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
24
“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’
25
Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dẹ lọ́pọ̀lọpọ̀;
26
Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
27
Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fí ẹnu mi kò ọwọ́ mi:
28
Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn Onidàájọ́ ní bẹ̀wò. Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
29
“Bí ó bá ṣepé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó korìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéra sókè, nígbà tí ibi bá a.
30
Bẹ́ẹ̀ èmí kò sì jẹ ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífi ègún sí ọkàn rẹ̀.
31
Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?
32
(Àléjò kò wọ̀ ni ìgboro rí; èmí sí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.)
33
Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Ádámù, ni pápá, ẹ̀bi mi mọ́ ni àyà mi.
34
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí? Tàbí ẹ̀gan àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù? Tí mo fi p'ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi jáde sóde?
35
(“Ìbá ṣepé ẹnìkán le gbọ́ ti èmí! Kíyèsí i, àmi mi, kí Olódùmárè kí ó dá mi lóhùn! Kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí ọ̀ta mi ti kọ!
36
Nítòótọ́ èmí ìbá gbé e le èjìká mi, èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
37
Èmi ìbá sì sọ iye ìsísẹ̀ mi fún un, bí ọmọ aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
38
“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
39
Bí mo bá jẹ èṣo oko mi láìsánwọ́ tàbi tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
40
kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò àlìkámà, àti èpò búburú dípò ọkà bárlè.” Ọ̀rọ̀ Jóòbù parí.
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 32 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42