bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 24
Job 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 25 →
1
“Se bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmárè fún ìdájọ́, èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
2
Díẹ̀ nínú wọn a ṣún àmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n sì ji wọn.
3
Wọ́n á sì dà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá-màlúù opó ní ohun ògo.
4
Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn talákà àyé a sá pamọ́ pọ̀.
5
Kíyèsí i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ nínú ijù ni àwọn talákà ijáde lọ sí iṣẹ́ wọn; Wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn
6
Olúkulùkù a sì ṣa ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
7
Ní hòòhò ni wọn má a sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
8
Ọ̀wàrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
9
Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ talákà. Nítorí gbèsè
10
Wọ́n rìn kiri níhòòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,
11
Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
12
Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè; fún ìrànlọ́wọ́ ṣíbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsí àṣìṣe náà.
13
“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó kọ̀ ìmọ́lẹ̀; Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14
Panipani a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa talákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.
15
Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró de àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi;’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16
Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17
Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
18
“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19
Ọ̀dá àti òru ní ímú omi ojọ-didi gbẹ, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú írun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
20
Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀, a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi;
21
Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó.
22
Ṣùgbọ́n ó fi ipá Ọlọ́run rẹ̀ fà alágbára lọ pẹ̀lú; Ó dìde, kò sí ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ dá lójú.
23
Ọlọ́run sì fi ìwà àìléwu fún un, àti nínú èyí ní a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24
A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀; wọ́n kọjá lọ, a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà, bí àwọn ẹlòmìíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí sírì itú ọkà bàbà.
25
“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsìn yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42