bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 29
Job 29
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 30 →
1
Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jóòbù sì tún tẹ̀ ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:
2
“Áà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pamímọ́;
3
Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;
4
Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi
5
Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
6
Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi, àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá.
7
“Nígbà tí mo jáde la àárin ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
8
Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹṣẹ̀ wọn;
9
Àwọn ọmọ aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sí sọ, wọn a sì fí ọwọ́ wọn lé ẹnu;
10
Àwọn ọmọ ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀mọ́ èrìgì ẹnu wọn.
11
Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;
12
Nítorí mo gbà talákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba, tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un
13
Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
14
Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
15
Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀ fún amúkùnún.
16
Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.
17
Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.
18
“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn.
19
Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.
20
Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi’
21
“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.
22
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.
23
Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò.
24
Èmi sì rẹ́rìn ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye síwọn.
25
Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn; mo jókòó bí ọba ní àárin ológun rẹ̀; mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń sọ̀fọ̀ nínú.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42