bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 14
Job 14
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 15 →
1
“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
2
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; Ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
3
Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
5
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7
“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.
8
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
9
Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi, yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10
Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù; Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?
11
“Bí omi tí i sàn nínú ipa odò, tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,
12
bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13
“Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14
Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15
Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16
Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17
A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.
18
“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19
Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20
Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21
Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsìí lára wọn.
22
Ṣùgbọ́n ẹran ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42