bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Job 36
Job 36
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 35
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 37 →
1
Elíhù sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:
2
“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́ nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3
Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4
Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5
“Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
6
Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
7
Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
8
Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9
Nígbà náà ni o ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ́lú ìgbéraga wọn.
10
Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedéédéé.
11
Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12
Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.
13
“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.
14
Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù.
15
Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn.
16
“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ láti inú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
17
Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18
Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bàà tàn ọ́; láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà.
19
Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbi ipa agbára rẹ?
20
Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn.
21
Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búrubú; Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
22
“Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípa agbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun?
23
Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un, tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?
24
Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti ènìyàn ni yín nínú orin.
25
Olúkúlùkù a máa rí i; ènìyàn a máa wòó ní òkèrè,
26
Kíyèsí i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.
27
“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi ọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò,
28
tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ń gbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.
29
Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànká àwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
30
Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.
31
Nitorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílè èdè ènìyàn; ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
32
Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèje ó sì rán sí ẹni olódì.
33
Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní; ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!
← Chapter 35
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 37 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42