bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 10
Job 10
Yoruba 2010
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 11 →
1
“Ayé sú mi, nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn; n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn.
2
N óo sọ fún Ọlọrun pé kí ó má dá mi lẹ́bi; kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdí tí ó fi ń bá mi jà.
3
Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrun pé kí o máa ni eniyan lára, kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi?
4
Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan? Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i?
5
Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí? Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan?
6
Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi, tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?
7
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.
8
Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi, ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.
9
Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí, ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?
10
Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà, tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?
11
Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí, tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.
12
O fún mi ní ìyè, o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.
13
Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ, mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé,
14
bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi, o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà.
15
Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé, ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn, nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.
16
Bí mo bá ṣe àṣeyọrí, o óo máa lépa mi bíi kinniun; ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára.
17
O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí, O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ, O mú kí ogun mìíràn dó tì mí.
18
“Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi? Ìbá sàn kí n ti kú, kí ẹnikẹ́ni tó rí mi.
19
Wọn ìbá má bí mi rárá, kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì.
20
Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé? Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀,
21
kí n tó pada síbi tí mo ti wá, sí ibi òkùnkùn biribiri,
22
ibi òkùnkùn ati ìdàrúdàpọ̀, níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti dàbí òkùnkùn.”
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42