bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 33
Job 33
Yoruba 2010
← Chapter 32
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 34 →
1
“Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
2
Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ.
3
Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀, ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ.
4
Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi, èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.
5
“Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn. Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára, kí o sì múra láti wí àwíjàre.
6
Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun, amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.
7
Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.
8
“Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi, mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.
9
O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀, ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan.
10
Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀, ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,
11
ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀, ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.
12
“Jobu, n óo dá ọ lóhùn, nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Ọlọrun ju eniyan lọ.
13
Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?
14
Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.
15
Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru, nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,
16
Ọlọrun a máa ṣí wọn létí, a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,
17
kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn, kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn;
18
kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun, kí ó má baà kú ikú idà.
19
“OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀; a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀.
20
Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ, oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.
21
Eniyan á rù hangangan, wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.
22
Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì, ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.
23
Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀, tí ó wà fún un bí onídùúró, àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun, tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,
24
tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé, ‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì, mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’
25
Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde, kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;
26
nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀. Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun, yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé
27
Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé, ‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po, ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi.
28
Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú, mo sì wà láàyè.’
29
“Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan, lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta,
30
láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú, kí ó lè wà láàyè.
31
“Gbọ́, ìwọ Jobu, farabalẹ̀, dákẹ́ kí o lè gbọ́ ohun tí n óo sọ.
32
Bí o bá ní ohunkohun láti sọ, dá mi lóhùn; sọ̀rọ̀, nítorí pé mo fẹ́ dá ọ láre ni.
33
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tẹ́tí sí mi; farabalẹ̀, n óo sì kọ́ ọ lọ́gbọ́n.”
← Chapter 32
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 34 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42