bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 22
Job 22
Yoruba 2010
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 23 →
1
Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,
2
“Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún.
3
Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?
4
Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?
5
Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?
6
O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.
7
O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.
8
Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.
9
O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.
10
Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.
11
Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12
“Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀ àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ, bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!
13
Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’ Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?
14
Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran, ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run.
15
“Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé; ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?
16
A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó, a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.
17
Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’
18
Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn— ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.
19
Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,
20
wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun, iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’
21
“Nisinsinyii gba ti Ọlọrun, kí o sì wà ní alaafia; kí ó lè dára fún ọ.
22
Gba ìtọ́ni rẹ̀, kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn.
23
Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀, tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ,
24
bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀, tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò,
25
bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ, ati fadaka olówó iyebíye rẹ,
26
nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.
27
Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́, o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28
Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe, yóo ṣeéṣe fún ọ, ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.
29
Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀, a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.
30
A máa gba àwọn aláìṣẹ̀, yóo sì gbà ọ́ là, nípa ìwà mímọ́ rẹ.”
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 23 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42