bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 16
Job 16
Yoruba 2010
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 17 →
1
Jobu bá dáhùn pé,
2
“Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí, ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín.
3
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin? Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí?
4
Bí ẹ bá wà ní ipò mi, èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí, kí n da ọ̀rọ̀ bò yín, kí n sì máa mi orí si yín.
5
Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun, kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.
6
“Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí, bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi?
7
Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara, ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro.
8
Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí; rírù tí mo rù ta àbùkù mi, ó sì hàn lójú mi.
9
Ó ti fi ibinu fà mí ya, ó sì kórìíra mi; ó pa eyín keke sí mi; ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí.
10
Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń gbá mi létí, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi.
11
Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́, ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà.
12
Nígbà tí ó dára fún mi, ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀, ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀, ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́; ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí.
13
Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká, ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi, ó sì tú òróòro mi jáde.
14
Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo, ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.
15
“Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀.
16
Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n, omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn,
17
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi, adura mi sì mọ́.
18
“Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀, má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo.
19
Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run, alágbàwí mi sì ń bẹ lókè.
20
Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, mo sì ń sọkún sí Ọlọrun,
21
ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun, bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan.
22
Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i, n óo lọ àjò àrèmabọ̀.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42