bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 30
Job 30
Yoruba 2010
← Chapter 29
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 31 →
1
“Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.
2
Kí ni anfaani agbára wọn fún mi, àwọn tí wọn kò lókun ninu?
3
Ninu ìyà ati ebi, wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.
4
Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ, àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5
Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan, wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6
Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá, ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7
Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó, wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8
Àwọn aláìlóye ọmọ, àwọn ọmọ eniyan lásán, àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.
9
“Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn, mo ti di àmúpòwe.
10
Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn, wọ́n ń rí mi sá, ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.
11
Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera, ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀, wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn.
12
Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi, wọ́n lé mi kúrò, wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.
13
Wọ́n dínà mọ́ mi, wọ́n dá kún wahala mi, kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.
14
Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé, wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.
15
Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi, wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́, ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.
16
“Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi, ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.
17
Ní òru, egungun ń ro mí, ìrora mi kò sì dínkù.
18
Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi, ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.
19
Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀, mo dàbí eruku ati eérú.
20
“Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn, mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.
21
O dojú ibinu kọ mí, o fi agbára rẹ bá mi jà.
22
O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́, ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún láàrin ariwo ìjì líle.
23
Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú, ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.
24
Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira, dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?
25
Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí, tí mo sì káàánú àwọn aláìní.
26
Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere, ibi ní ń bá mi. Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn ni mò ń rí.
27
Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀, ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.
28
Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri, mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.
29
Mò ń kígbe arò bí ajáko, mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.
30
Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó, egungun mi gbóná fún ooru.
31
Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi, ẹkún sì dípò ohùn fèrè.
← Chapter 29
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 31 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42